1 Kronika 9:3
1 Chronicles 9:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn tí ó wá láti Juda láti Benjamini àti láti Efraimu àti Manase tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu jẹ́:
1 Chronicles 9:3 in English
1 Chronicles 9:3 · Berean Standard Bible
These were some of the descendants of Judah, Benjamin, Ephraim, and Manasseh who lived in Jerusalem:
Context
1Gbogbo Israẹli ni a kọ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Israẹli. Àwọn ènìyàn Juda ni a kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli nítorí àìṣòótọ́ wọn. 2Nísinsin yìí, àwọn tí ó kọ́kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa. 3Àwọn tí ó wá láti Juda láti Benjamini àti láti Efraimu àti Manase tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu jẹ́: 4Uttai ọmọ Ammihudu, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ìran ọmọ Peresi ọmọ Juda. 5Àti nínú ará Ṣilo:
Asaiah àkọ́bí àti àwọn ọmọ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.