1 Kronika 9:23
1 Chronicles 9:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́.
1 Chronicles 9:23 in English
1 Chronicles 9:23 · Berean Standard Bible
So they and their descendants were assigned to guard the gates of the house of the LORD—the house called the Tent.
Context
21Sekariah, ọmọ Meṣelemiah jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àbáwọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé. 22Gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àwọn ìloro jẹ́ igba ó lé méjìlá (212). A ka àwọn wọ̀nyí nípa ìdílé ní ìletò wọn.
Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Samuẹli, aríran, nítorí òtítọ́ wọn. 23Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́. 24Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà-oòrùn, ìwọ̀-oòrùn àríwá àti gúúsù. 25Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín iṣẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.