Native Bible

1 Chronicles 9:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín iṣẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje.

1 Chronicles 9:25 in English

1 Chronicles 9:25 · Berean Standard Bible

Their relatives came from their villages at fixed times to serve with them for seven-day periods.

Context

23Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́. 24Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà-oòrùn, ìwọ̀-oòrùn àríwá àti gúúsù. 25Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín iṣẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje. 26Ṣùgbọ́n àwọn olórí alábojútó ẹnu-ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìṣúra ní ilé Ọlọ́run. 27Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Ọlọ́run ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ, wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.