Native Bible

1 Chronicles 7:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọmọ Naftali: Jasieli, Guni, Jeseri àti Ṣallumu—ọmọ rẹ̀ nípa Biliha.

1 Chronicles 7:13 in English

1 Chronicles 7:13 · Berean Standard Bible

The sons of Naphtali: Jahziel,* Guni, Jezer, and Shallum *—the descendants of Bilhah.

Context

11Gbogbo àwọn ọmọ Jediaeli jẹ́ olórí. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún ó lé nígba (17,200) akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetán láti jáde lọ sí ogun. 12Àti Ṣuppimu, àti Huppimu, àwọn ọmọ Iri, àti Huṣimu, àwọn ọmọ Aheri. 13Àwọn ọmọ Naftali: Jasieli, Guni, Jeseri àti Ṣallumu—ọmọ rẹ̀ nípa Biliha. 14Àwọn ìran ọmọ Manase: Asrieli jẹ́ ìran ọmọ rẹ̀ ní ipasẹ̀ àlè rẹ̀ ará Aramu ó bí Makiri baba Gileadi. 15Makiri sì mú ìyàwó láti àárín àwọn ará Huppimu àti Ṣuppimu. Orúkọ arábìnrin rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a máa jẹ́ Selofehadi, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.