1 Kronika 28:17
1 Chronicles 28:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ìwọ̀n kìkì wúrà fún àwọn àmúga ìjẹun, àwọn ìbùwọ́n ọpọ́n àti àwọn ìkòkò ìpọnmi; ìwọ̀n wúrà fún gbogbo àwopọ̀kọ́ fàdákà;
1 Chronicles 28:17 in English
1 Chronicles 28:17 · Berean Standard Bible
the weight of the pure gold for the forks, sprinkling bowls, and pitchers; the weight of each gold dish; the weight of each silver bowl;
Context
15ìwọ̀n wúrà fún ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn, fún ìwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn; àti ìwọ̀n fàdákà ìdúró fìtílà fàdákà àti àwọn fìtílà rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlò ti gbogbo ìdúró fìtílà. 16Ìwọ̀n ti wúrà fun tábìlì, tábìlì fún àkàrà tí a yà sọ́tọ̀; ìwọ̀n fàdákà fún àwọn tábìlì fàdákà; 17ìwọ̀n kìkì wúrà fún àwọn àmúga ìjẹun, àwọn ìbùwọ́n ọpọ́n àti àwọn ìkòkò ìpọnmi; ìwọ̀n wúrà fún gbogbo àwopọ̀kọ́ fàdákà; 18àti ìwọ̀n ìdá wúrà fún pẹpẹ tùràrí ó fún un ní ètò fún kẹ̀kẹ́, ìyẹn ni pé àwọn ìdúró kérúbù wúrà tí wọ́n tan iye wọn ká, wọ́n sì bo àpótí ẹ̀rí Olúwa. 19“Gbogbo èyí,” ni Dafidi wí pé, “Èmi ní kíkọ sílẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa sórí mi, ó sì fún mí ní ìmọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ ètò yìí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.