Native Bible

1 Chronicles 28:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Dafidi fi àpẹẹrẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀ ti ìloro àti ti ilé Olúwa náà, kíkọ́ ọ rẹ̀, àti ti ibi ìṣúra rẹ̀, àti ti iyàrá òkè rẹ̀, àti ti ìyẹ̀wù rẹ̀ àti ti ibùjókòó àánú.

1 Chronicles 28:11 in English

1 Chronicles 28:11 · Berean Standard Bible

Then David gave his son Solomon the plans for the portico of the temple,* its buildings, storehouses, upper rooms, inner rooms, and the room for the mercy seat.*

Context

9“Àti ìwọ, ọmọ mi Solomoni, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí Olúwa ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò. Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ títí láé. 10Gbèrò báyìí nítorí tí Olúwa ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí ilé tí a yà sí mímọ́ fún Olúwa. Jẹ́ alágbára kí ó sì ṣe iṣẹ́ náà.” 11Nígbà náà ni Dafidi fi àpẹẹrẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀ ti ìloro àti ti ilé Olúwa náà, kíkọ́ ọ rẹ̀, àti ti ibi ìṣúra rẹ̀, àti ti iyàrá òkè rẹ̀, àti ti ìyẹ̀wù rẹ̀ àti ti ibùjókòó àánú. 12Ó fún un ní àwọn ètò gbogbo èyí tí ẹ̀mí ti fi sí ọkàn rẹ̀ fún ti ààfin ilé Olúwa àti gbogbo yàrá tí ó yíká fún ìṣúra ilé Ọlọ́run àti fún ìṣúra fún ohun yíyà sọ́tọ̀. 13Ó fún un ní àwọn ìlànà fún ìpín ti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa àti fún gbogbo ohun èlò tí wọn ó lò nínú ìsìn rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.