Native Bible

1 Chronicles 28:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Àti ìwọ, ọmọ mi Solomoni, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí Olúwa ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò. Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ títí láé.

1 Chronicles 28:9 in English

1 Chronicles 28:9 · Berean Standard Bible

As for you, Solomon my son, know the God of your father and serve Him wholeheartedly and with a willing mind, for the LORD searches every heart and understands the intent of every thought. If you seek Him, He will be found by you; but if you forsake Him, He will reject you forever.

Context

7Èmi yóò fi ìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ títí láé tí kò bá kọ̀ láti gbé àṣẹ àti òfin mi jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe é ní àsìkò yìí. 8“Bẹ́ẹ̀ ni, nísinsin yìí, èmi pàṣẹ fún ọ ní ojú gbogbo Israẹli àti ní ti ìpéjọpọ̀ tí Olúwa, àti ní etí ìgbọ́ Ọlọ́run wa. Ṣọ́ra kó o sì tẹ̀lé gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ kí ìwọ kí ó le jogún ilẹ̀ dáradára yìí, kí o sì mú un lọ síwájú gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ fún àwọn ìran ọmọ rẹ títí láé. 9“Àti ìwọ, ọmọ mi Solomoni, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí Olúwa ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò. Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ títí láé. 10Gbèrò báyìí nítorí tí Olúwa ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí ilé tí a yà sí mímọ́ fún Olúwa. Jẹ́ alágbára kí ó sì ṣe iṣẹ́ náà.” 11Nígbà náà ni Dafidi fi àpẹẹrẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀ ti ìloro àti ti ilé Olúwa náà, kíkọ́ ọ rẹ̀, àti ti ibi ìṣúra rẹ̀, àti ti iyàrá òkè rẹ̀, àti ti ìyẹ̀wù rẹ̀ àti ti ibùjókòó àánú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.