1 Kronika 28:13
1 Chronicles 28:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó fún un ní àwọn ìlànà fún ìpín ti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa àti fún gbogbo ohun èlò tí wọn ó lò nínú ìsìn rẹ̀.
1 Chronicles 28:13 in English
1 Chronicles 28:13 · Berean Standard Bible
for the divisions of the priests and Levites, for all the work of service in the house of the LORD, and for all the articles of service in the house of the LORD:
Context
11Nígbà náà ni Dafidi fi àpẹẹrẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀ ti ìloro àti ti ilé Olúwa náà, kíkọ́ ọ rẹ̀, àti ti ibi ìṣúra rẹ̀, àti ti iyàrá òkè rẹ̀, àti ti ìyẹ̀wù rẹ̀ àti ti ibùjókòó àánú. 12Ó fún un ní àwọn ètò gbogbo èyí tí ẹ̀mí ti fi sí ọkàn rẹ̀ fún ti ààfin ilé Olúwa àti gbogbo yàrá tí ó yíká fún ìṣúra ilé Ọlọ́run àti fún ìṣúra fún ohun yíyà sọ́tọ̀. 13Ó fún un ní àwọn ìlànà fún ìpín ti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa àti fún gbogbo ohun èlò tí wọn ó lò nínú ìsìn rẹ̀. 14Ó yàn ìwọ̀n wúrà fún gbogbo ohun èlò wúrà tí a ó lò níbi oríṣìí ìsìn, àti ìwọ̀n fàdákà fún gbogbo ohun èlò fàdákà tí a ó lò fún oríṣìí ìsìn, 15ìwọ̀n wúrà fún ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn, fún ìwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn; àti ìwọ̀n fàdákà ìdúró fìtílà fàdákà àti àwọn fìtílà rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlò ti gbogbo ìdúró fìtílà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.