1 Kronika 26:28
1 Chronicles 26:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Samuẹli aríran láti nípasẹ̀ Saulu ọmọ Kiṣi, Abneri ọmọ Neri àti Joabu ọmọ Seruiah gbogbo ohun tí a yà sọ́tọ̀ sì wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣelomiti àti àwọn ìbátan rẹ̀.
1 Chronicles 26:28 in English
1 Chronicles 26:28 · Berean Standard Bible
Everything that had been dedicated by Samuel the seer, Saul son of Kish, Abner son of Ner, and Joab son of Zeruiah, along with everything else that was dedicated, was under the care of Shelomith and his brothers.
Context
26Ṣelomiti àti àwọn ìbátan rẹ̀ jẹ́ alábojútó ilé ìṣúra fún àwọn ohun tí à ti yà sọ́tọ̀ nípa ọba Dafidi, nípasẹ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti nípasẹ̀ alákòóso ọmọ-ogun mìíràn. 27Díẹ̀ nínú ìkógun tí wọ́n kó nínú ogun ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún títún ilé Olúwa ṣe. 28Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Samuẹli aríran láti nípasẹ̀ Saulu ọmọ Kiṣi, Abneri ọmọ Neri àti Joabu ọmọ Seruiah gbogbo ohun tí a yà sọ́tọ̀ sì wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣelomiti àti àwọn ìbátan rẹ̀. 29Láti ọ̀dọ̀ àwọn Isari:
Kenaniah àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni a pín iṣẹ́ ìsìn fún kúrò ní apá ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn oníṣẹ́ àti àwọn adájọ́ lórí Israẹli. 30Láti ọ̀dọ̀ àwọn Hebroni:
Haṣabiah àti àwọn ìbátan rẹ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán (17,000) ọkùnrin alágbára ní ó dúró ni Israẹli, ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani fún gbogbo iṣẹ́ Olúwa àti fún iṣẹ́ ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.