1 Kronika 26:27
1 Chronicles 26:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Díẹ̀ nínú ìkógun tí wọ́n kó nínú ogun ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún títún ilé Olúwa ṣe.
1 Chronicles 26:27 in English
1 Chronicles 26:27 · Berean Standard Bible
They had dedicated some of the plunder from their battles to the repair of the house of the LORD.
Context
25Àwọn ìbátan rẹ̀ nípasẹ̀ Elieseri: Rehabiah ọmọ rẹ̀, Jeṣaiah ọmọ rẹ̀, Joramu ọmọ rẹ̀, Sikri ọmọ rẹ̀, Ṣelomiti ọmọ rẹ̀. 26Ṣelomiti àti àwọn ìbátan rẹ̀ jẹ́ alábojútó ilé ìṣúra fún àwọn ohun tí à ti yà sọ́tọ̀ nípa ọba Dafidi, nípasẹ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti nípasẹ̀ alákòóso ọmọ-ogun mìíràn. 27Díẹ̀ nínú ìkógun tí wọ́n kó nínú ogun ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún títún ilé Olúwa ṣe. 28Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Samuẹli aríran láti nípasẹ̀ Saulu ọmọ Kiṣi, Abneri ọmọ Neri àti Joabu ọmọ Seruiah gbogbo ohun tí a yà sọ́tọ̀ sì wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣelomiti àti àwọn ìbátan rẹ̀. 29Láti ọ̀dọ̀ àwọn Isari:
Kenaniah àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni a pín iṣẹ́ ìsìn fún kúrò ní apá ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn oníṣẹ́ àti àwọn adájọ́ lórí Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.