1 Kronika 25:2
1 Chronicles 25:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nínú àwọn ọmọ Asafu: Sakkuri, Josẹfu, Netaniah àti Asarela, àwọn ọmọ Asafu ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó Asafu, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìbojútó ọba.
1 Chronicles 25:2 in English
1 Chronicles 25:2 · Berean Standard Bible
From the sons of Asaph: Zaccur, Joseph, Nethaniah, and Asarelah. These sons of Asaph were under the direction of Asaph, who prophesied under the direction of the king.
Context
1Pẹ̀lúpẹ̀lú Dafidi àti àwọn olórí àwọn ọmọ-ogun, ó sì yà díẹ̀ sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Asafu, Hemani àti Jedutuni fún ìsìn àsọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn àti kimbali. Èyí sì ní àwọn iye àwọn ọkùnrin ẹni tí ó ṣe oníṣẹ́ ìsìn yìí. 2Nínú àwọn ọmọ Asafu:
Sakkuri, Josẹfu, Netaniah àti Asarela, àwọn ọmọ Asafu ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó Asafu, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìbojútó ọba. 3Gẹ́gẹ́ bí ti Jedutuni, nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀:
Gedaliah, Seri, Jeṣaiah, Ṣimei, Haṣabiah àti Mattitiah, mẹ́fà nínú gbogbo wọn, lábẹ́ ìbojútó baba wọn Jedutuni, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ó lo dùùrù láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. 4Gẹ́gẹ́ bí ti Hemani, nínú àwọn ọmọ rẹ̀:
Bukkiah, Mattaniah, Usieli, Ṣubaeli àti Jerimoti; Hananiah, Hanani, Eliata, Giddalti, àti Romamtieseri, Joṣbekaṣa, Malloti, Hotiri, Mahasiotu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.