Native Bible

1 Chronicles 25:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gẹ́gẹ́ bí ti Hemani, nínú àwọn ọmọ rẹ̀: Bukkiah, Mattaniah, Usieli, Ṣubaeli àti Jerimoti; Hananiah, Hanani, Eliata, Giddalti, àti Romamtieseri, Joṣbekaṣa, Malloti, Hotiri, Mahasiotu.

1 Chronicles 25:4 in English

1 Chronicles 25:4 · Berean Standard Bible

From the sons of Heman: Bukkiah, Mattaniah, Uzziel, Shebuel,* Jerimoth,* Hananiah, Hanani, Eliathah, Giddalti, Romamti-ezer, Joshbekashah, Mallothi, Hothir, and Mahazioth.

Context

2Nínú àwọn ọmọ Asafu: Sakkuri, Josẹfu, Netaniah àti Asarela, àwọn ọmọ Asafu ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó Asafu, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìbojútó ọba. 3Gẹ́gẹ́ bí ti Jedutuni, nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀: Gedaliah, Seri, Jeṣaiah, Ṣimei, Haṣabiah àti Mattitiah, mẹ́fà nínú gbogbo wọn, lábẹ́ ìbojútó baba wọn Jedutuni, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ó lo dùùrù láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. 4Gẹ́gẹ́ bí ti Hemani, nínú àwọn ọmọ rẹ̀: Bukkiah, Mattaniah, Usieli, Ṣubaeli àti Jerimoti; Hananiah, Hanani, Eliata, Giddalti, àti Romamtieseri, Joṣbekaṣa, Malloti, Hotiri, Mahasiotu. 5Gbogbo àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Hemani àti wòlíì ọba. Wọ́n sì fi wọ́n fún nípa ìlérí Ọlọ́run láti máa gbé ìwo sókè. Ọlọ́run sì fún Hemani ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá àti àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta. 6Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó àwọn baba wọn fún ohun èlò orin ilé Olúwa, pẹ̀lú kimbali, ohun èlò orin olókùn àti dùùrù, fún ìsìn ilé Olúwa. Asafu, Jedutuni àti Hemani sì wà lábẹ́ ọba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.