Native Bible

1 Chronicles 23:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jahati sì ni alákọ́kọ́ Sinah sì ni ẹlẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n Jeuṣi àti Beriah kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.

1 Chronicles 23:11 in English

1 Chronicles 23:11 · Berean Standard Bible

Jahath was the first and Zizah was the second; but Jeush and Beriah did not have many sons, so they were counted as one family and received a single assignment.

Context

9Àwọn ọmọ Ṣimei: Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn. Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani. 10Àti ọmọ Ṣimei: Jahati, Sina, Jeuṣi àti Beriah. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣimei mẹ́rin ni gbogbo wọn. 11Jahati sì ni alákọ́kọ́ Sinah sì ni ẹlẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n Jeuṣi àti Beriah kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan. 12Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli mẹ́rin ni gbogbo wọn. 13Àwọn ọmọ Amramu. Aaroni àti Mose. A sì ya Aaroni sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rú ẹbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjíṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ rẹ̀ títí láéláé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.