Native Bible

1 Chronicles 21:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọdún mẹ́ta ìyàn, tàbí ìparun ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́ta idà Olúwa ọjọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn angẹli Olúwa láti pa gbogbo agbègbè Israẹli run.’ Nísinsin yìí ǹjẹ́, rò ó wò, èsì wo ni èmi yóò mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.”

1 Chronicles 21:12 in English

1 Chronicles 21:12 · Berean Standard Bible

between three years of famine, three months of being swept away * before your enemies and overtaken by their swords, or three days of the sword of the LORD—days of plague upon the land, with the angel of the LORD ravaging every part of Israel.’ Now then, decide how I should reply to Him who sent me.”

Context

10“Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ” 11Bẹ́ẹ̀ ni Gadi tọ Dafidi wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Yan fún ara rẹ. 12Ọdún mẹ́ta ìyàn, tàbí ìparun ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́ta idà Olúwa ọjọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn angẹli Olúwa láti pa gbogbo agbègbè Israẹli run.’ Nísinsin yìí ǹjẹ́, rò ó wò, èsì wo ni èmi yóò mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.” 13Dafidi sì wí fún Gadi pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí èmi kí ó ṣubú sí ọwọ́ Olúwa nísinsin yìí, nítorí tí àánú rẹ̀ pọ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí èmi kí o ṣubú sí ọwọ́ àwọn ènìyàn.” 14Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa rán àjàkálẹ̀-ààrùn lórí Israẹli, àwọn tí ó ṣubú ní Israẹli jẹ́ ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.