1 Kronika 2:23
1 Chronicles 2:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
(Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri baba Gileadi.
1 Chronicles 2:23 in English
1 Chronicles 2:23 · Berean Standard Bible
But Geshur and Aram captured Havvoth-jair,* along with Kenath and its sixty surrounding villages. All these were descendants of Machir the father of Gilead.
Context
21Nígbà tí ó yá, Hesroni sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Makiri baba Gileadi (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Segubu. 22Segubu sì jẹ́ baba Jairi, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́tàlélógún ní ilẹ̀ Gileadi. 23(Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.)
Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri baba Gileadi. 24Lẹ́yìn tí Hesroni sì kú ni Kalebu Efrata, Abijah ìyàwó rẹ̀ ti Hesroni sì bí Aṣihuri baba Tekoa fún un. 25Ọmọ Jerahmeeli àkọ́bí Hesroni:
Ramu ọmọ àkọ́bí rẹ̀ Buna, Oreni, Osemu àti Ahijah.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.