Native Bible

1 Chronicles 19:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àkókò yí, Nahaṣi ọba àwọn ará Ammoni sì kú, ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

1 Chronicles 19:1 in English

1 Chronicles 19:1 · Berean Standard Bible

Some time later, Nahash king of the Ammonites died and was succeeded by his son.

Context

1Ní àkókò yí, Nahaṣi ọba àwọn ará Ammoni sì kú, ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 2Dafidi rò wí pé èmi yóò fi inú rere hàn sí Hanuni ọmọ Nahaṣi, nítorí baba a rẹ̀ fi inú rere hàn sí mi. Bẹ́ẹ̀ ni, Dafidi rán àwọn aṣojú lọ láti lọ fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí Hanuni ní ti baba a rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dafidi wá sí ọ̀dọ̀ Hanuni ní ilẹ̀ àwọn ará Ammoni láti fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí i. 3Àwọn ọkùnrin ọlọ́lá ti Ammoni sọ fún Hanuni pé, “Ṣé ìwọ rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nípa rírán àwọn olùtùnú sí ọ? Ṣé àwọn ọkùnrin rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti rìn wò àti láti bì í ṣubú, àti láti ṣe ayọ́lẹ̀wò ilẹ̀ náà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.