1 Kronika 17:3
1 Chronicles 17:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Natani wá, wí pé:
1 Chronicles 17:3 in English
1 Chronicles 17:3 · Berean Standard Bible
But that night the word of God came to Nathan, saying,
Context
1Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani wòlíì pé, “Èmi nìyí, tí ń gbé inú ààfin kedari nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa wà lábẹ́ àgọ́.” 2Natani dá Dafidi lóhùn pé, “Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.” 3Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Natani wá, wí pé: 4“Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé. 5Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.