1 Kronika 17:4
1 Chronicles 17:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé.
1 Chronicles 17:4 in English
1 Chronicles 17:4 · Berean Standard Bible
“Go and tell My servant David that this is what the LORD says: You are not the one to build Me a house in which to dwell.
Context
2Natani dá Dafidi lóhùn pé, “Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.” 3Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Natani wá, wí pé: 4“Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé. 5Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé. 6Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Israẹli rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkan kan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Israẹli, tí èmí pàṣẹ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yin kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kedari kọ́ fún mi?” ’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.