1 Kronika 17:15
1 Chronicles 17:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Natani ròyìn fún Dafidi gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti ìfihàn yí.
1 Chronicles 17:15 in English
1 Chronicles 17:15 · Berean Standard Bible
So Nathan relayed to David all the words of this entire vision.
Context
13Èmi yóò jẹ́ baba rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo ṣe mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú rẹ̀. 14Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ rẹ̀ ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ” 15Natani ròyìn fún Dafidi gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti ìfihàn yí. 16Nígbà náà, ọba Dafidi wọlé lọ, ó sì jókòó níwájú Olúwa ó sì wí pé,
“Ta ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, àti ki ni ìdílé mi, tí ìwọ mú mi dé ibí? 17Pẹ̀lú bí ẹni pé èyí kò tó lójú rẹ, Ọlọ́run, ìwọ ti sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú ilé ìránṣẹ́ rẹ. Ìwọ ti wò mí bí ẹni pé èmi ni ẹni gbígbéga jù láàrín àwọn ọkùnrin Olúwa Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.