Native Bible

1 Chronicles 15:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kenaniah olórí àwọn ará Lefi ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa rẹ̀.

1 Chronicles 15:22 in English

1 Chronicles 15:22 · Berean Standard Bible

Chenaniah the head Levite was the director of the music because he was highly skilled.

Context

20Sekariah, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, àti Unni, Eliabu, Maaseiah àti Benaiah àwọn tí ó gbọdọ̀ ta ohun èlò orin olókùn gẹ́gẹ́ bí alamoti, 21àti Mattitiah, Elifelehu, Mikneiah, Obedi-Edomu, Jeieli àti Asasiah ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn gooro, láti darí gẹ́gẹ́ bí ṣeminiti. 22Kenaniah olórí àwọn ará Lefi ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa rẹ̀. 23Berekiah àti Elkana ni kí ó wà gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí. 24Ṣebaniah, Jehoṣafati, Netaneli, Amasai, Sekariah, Benaiah àti Elieseri ní àwọn àlùfáà, tí o ń fún ìpè níwájú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Obedi-Edomu àti Jehiah ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.