1 Kronika 15:20
1 Chronicles 15:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sekariah, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, àti Unni, Eliabu, Maaseiah àti Benaiah àwọn tí ó gbọdọ̀ ta ohun èlò orin olókùn gẹ́gẹ́ bí alamoti,
1 Chronicles 15:20 in English
1 Chronicles 15:20 · Berean Standard Bible
Zechariah, Aziel,* Shemiramoth, Jehiel, Unni, Eliab, Maaseiah, and Benaiah were to play the harps according to Alamoth.*
Context
18àti pẹ̀lú wọn àwọn arákùnrin wọn tí a yàn bí olùrànlọ́wọ́ wọn: Sekariah, Jaasieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Unni, Eliabu, Benaiah, Maaseiah, Mattitiah, Elifelehu, Mikimeiah, àti Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn aṣọ́bodè. 19Àwọn akọrin sì ni Hemani, Asafu, àti Etani ti àwọn ti kimbali idẹ tí ń dún kíkan; 20Sekariah, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, àti Unni, Eliabu, Maaseiah àti Benaiah àwọn tí ó gbọdọ̀ ta ohun èlò orin olókùn gẹ́gẹ́ bí alamoti, 21àti Mattitiah, Elifelehu, Mikneiah, Obedi-Edomu, Jeieli àti Asasiah ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn gooro, láti darí gẹ́gẹ́ bí ṣeminiti. 22Kenaniah olórí àwọn ará Lefi ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.