Sefaniah 3:4
Zephaniah 3:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn wòlíì rẹ̀ gbéraga, wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn. Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti ba ibi mímọ́ jẹ́, wọ́n sì rú òfin.
Zephaniah 3:4 in English
Zephaniah 3:4 · Berean Standard Bible
Her prophets are reckless, faithless men. Her priests profane the sanctuary; they do violence to the law.
Context
2Òun kò gbọ́rọ̀ sí ẹnikẹ́ni,
òun kò gba ìtọ́ni,
òun kò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa,
bẹ́ẹ̀ ni òun kò súnmọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀. 3Àwọn olórí rẹ̀ jẹ́ kìnnìún tí ń ké ramúramù,
àwọn onídàájọ́ rẹ̀, ìkookò àṣálẹ́ ni wọn,
wọn kò sì fi nǹkan kan kalẹ̀ fún òwúrọ̀. 4Àwọn wòlíì rẹ̀ gbéraga,
wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn.
Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti ba ibi mímọ́ jẹ́,
wọ́n sì rú òfin. 5Olúwa ni àárín rẹ̀ jẹ́ olódodo;
kì yóò ṣe ohun tí kò tọ̀nà.
Àràárọ̀ ni ó máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sí ìmọ́lẹ̀,
kì í sì kùnà ní gbogbo ọjọ́ tuntun,
síbẹ̀ àwọn aláìṣòótọ́ kò mọ ìtìjú. 6“Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,
ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́.
Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní òfo
tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnìkankan kò kọjá níbẹ̀.
Ìlú wọn parun tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí
ẹnìkan tí yóò ṣẹ́kù,
kò sì ní sí ẹnìkan rárá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.