Sefaniah 3:14
Zephaniah 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, kígbe sókè, ìwọ Israẹli! Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.
Zephaniah 3:14 in English
Zephaniah 3:14 · Berean Standard Bible
Sing for joy, O Daughter of Zion; shout aloud, O Israel! Be glad and rejoice with all your heart, O Daughter of Jerusalem!
Context
12Ṣùgbọ́n Èmi yóò fi àwọn ọlọ́kàn tútù
àti onírẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ni àárín rẹ̀,
wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa. 13Àwọn ìyókù Israẹli kì yóò hùwà ibi,
wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké.
Bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí
ahọ́n àrékérekè ní ẹnu wọn.
Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rùbà wọ́n.” 14Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
kígbe sókè, ìwọ Israẹli!
Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn,
ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu. 15Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì kúrò,
ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn.
Olúwa, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ;
ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́. 16Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé,
“Má ṣe bẹ̀rù Sioni;
má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.