Sefaniah 2:3
Zephaniah 2:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pàṣẹ. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú, bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.
Zephaniah 2:3 in English
Zephaniah 2:3 · Berean Standard Bible
Seek the LORD, all you humble of the earth who carry out His justice. Seek righteousness; seek humility. Perhaps you will be sheltered on the day of the LORD’s anger.
Context
1Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, àní ẹ kó ra yín jọ pọ̀
orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú, 2kí a tó pa àṣẹ náà, kí ọjọ́ náà tó kọjá bí ìyàngbò ọkà,
kí gbígbóná ìbínú Olúwa tó dé bá a yín,
kí ọjọ́ ìbínú Olúwa kí ó tó dé bá a yín. 3Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà,
ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pàṣẹ.
Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú,
bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa. 4Nítorí pé, a ó kọ Gasa sílẹ̀,
Aṣkeloni yóò sì dahoro.
Ní ọ̀sán gangan ni a ó lé Aṣdodu jáde,
a ó sì fa Ekroni tu kúrò. 5Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí Òkun,
ẹ̀yin ènìyàn ara Kereti;
ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kenaani,
ilẹ̀ àwọn ara Filistini.
“Èmi yóò pa yín run,
ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.