Sefaniah 1:8
Zephaniah 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ọjọ́ ẹbọ Olúwa, Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò, àti àwọn ọmọ ọba ọkùnrin, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ.
Zephaniah 1:8 in English
Zephaniah 1:8 · Berean Standard Bible
“On the Day of the LORD’s sacrifice I will punish the princes, the sons of the king, and all who are dressed in foreign apparel.
Context
6Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa;
àti àwọn tí kò tí wá Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.” 7Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa Olódùmarè,
nítorí tí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀.
Olúwa ti pèsè ẹbọ kan sílẹ̀,
ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́. 8“Ní ọjọ́ ẹbọ Olúwa,
Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò,
àti àwọn ọmọ ọba ọkùnrin,
pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ. 9Ní ọjọ́ náà, èmi yóò fi ìyà jẹ
gbogbo àwọn tí ó yẹra láti rìn lórí ìloro ẹnu-ọ̀nà,
tí wọ́n sì kún tẹmpili àwọn ọlọ́run wọn
pẹ̀lú ìwà ipá àti ẹ̀tàn. 10“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,
“Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà ibodè ẹja,
híhu láti ìhà kejì wá àti
ariwo ńlá láti òkè kékeré wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.