Sekariah 9:16
Zechariah 9:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà bí agbo ènìyàn rẹ̀: nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé, tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀.
Zechariah 9:16 in English
Zechariah 9:16 · Berean Standard Bible
On that day the LORD their God will save them as the flock of His people; for like jewels in a crown they will sparkle over His land.
Context
14Olúwa yóò sì fi ara hàn ní orí wọn;
ọfà rẹ̀ yóò sì jáde lọ bí mọ̀nàmọ́ná.
Olúwa Olódùmarè yóò sì fọn ìpè,
Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúúsù. 15Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n;
wọn ó sì jẹ ni run,
wọn ó sì tẹ òkúta kànnàkànnà mọ́lẹ̀;
wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì,
wọn ó sì kún bí ọpọ́n,
wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ. 16Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà
bí agbo ènìyàn rẹ̀:
nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé,
tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀. 17Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ sì tí pọ̀!
Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá,
àti ọtí wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.