Native Bible

Zechariah 9:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ti o ni ìrètí: àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́po méjì.

Zechariah 9:12 in English

Zechariah 9:12 · Berean Standard Bible

Return to your stronghold, O prisoners of hope; even today I declare that I will restore to you double.

Context

10Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Efraimu, àti ẹṣin ogun kúrò ni Jerusalẹmu, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun. Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí. Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun, àti láti odò títí de òpin ayé. 11Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun. 12Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ti o ni ìrètí: àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́po méjì. 13Èmi ó fa Juda le bí mo ṣe fa ọrun mi le, mo sì fi Efraimu kún un, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Sioni, sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Giriki, mo ṣe ọ́ bí idà alágbára. 14Olúwa yóò sì fi ara hàn ní orí wọn; ọfà rẹ̀ yóò sì jáde lọ bí mọ̀nàmọ́ná. Olúwa Olódùmarè yóò sì fọn ìpè, Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúúsù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.