Native Bible

Zechariah 8:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báyìí ni Olúwa wí, “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu. Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.”

Zechariah 8:3 in English

Zechariah 8:3 · Berean Standard Bible

This is what the LORD says: “I will return to Zion and dwell in Jerusalem. Then Jerusalem will be called the City of Truth, and the mountain of the LORD of Hosts will be called the Holy Mountain.”

Context

1Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá. 2Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Owú ńlá ńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńlá ńlá ni mo fi jowú fún un.” 3Báyìí ni Olúwa wí, “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu. Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.” 4Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jerusalẹmu, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó. 5Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.