Native Bible

Zechariah 7:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù karùn-ún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?”

Zechariah 7:3 in English

Zechariah 7:3 · Berean Standard Bible

by asking the priests of the house of the LORD of Hosts, as well as the prophets, “Should I weep and fast in the fifth month, as I have done these many years?”

Context

1Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ Sekariah wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kisleu tí ń ṣe oṣù kẹsànán. 2Nígbà tí wọ́n ènìyàn Beteli rán Ṣareseri àti Regemmeleki, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojúrere Olúwa. 3Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù karùn-ún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?” 4Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tọ̀ mí wá pé, 5“Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùn-ún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin ha ń gbààwẹ̀ yín fún?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.