Native Bible

Zechariah 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ìkógun fún ìránṣẹ́ wọn: ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi.

Zechariah 2:9 in English

Zechariah 2:9 · Berean Standard Bible

I will surely wave My hand over them, so that they will become plunder for their own servants. Then you will know that the LORD of Hosts has sent Me.”

Context

7“Gbà ara rẹ̀ sílẹ̀, ìwọ Sioni, ìwọ tí ó ń bà ọmọbìnrin Babeli gbé.” 8Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Lẹ́yìn ògo rẹ̀ ni a ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kó yin: nítorí ẹni tí ó tọ́ yin, ó tọ́ ọmọ ojú rẹ̀. 9Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ìkógun fún ìránṣẹ́ wọn: ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi. 10“Kọrin kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni. Nítorí èmi ń bọ̀ àti pé èmi yóò sì gbé àárín rẹ,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 11“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò dàpọ̀ mọ́ Olúwa ní ọjọ́ náà, wọn yóò sì di ènìyàn mi, èmi yóò sì gbé àárín rẹ, ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.