Sekariah 2:11
Zechariah 2:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò dàpọ̀ mọ́ Olúwa ní ọjọ́ náà, wọn yóò sì di ènìyàn mi, èmi yóò sì gbé àárín rẹ, ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí ọ.
Zechariah 2:11 in English
Zechariah 2:11 · Berean Standard Bible
“On that day many nations will join themselves to the LORD, and they will become My people. I will dwell among you, and you will know that the LORD of Hosts has sent Me to you.
Context
9Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ìkógun fún ìránṣẹ́ wọn: ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi. 10“Kọrin kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni. Nítorí èmi ń bọ̀ àti pé èmi yóò sì gbé àárín rẹ,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 11“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò dàpọ̀ mọ́ Olúwa ní ọjọ́ náà, wọn yóò sì di ènìyàn mi, èmi yóò sì gbé àárín rẹ, ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí ọ. 12Olúwa yóò sì jogún Juda ìní rẹ̀, ni ilẹ̀ mímọ́, yóò sì tún yan Jerusalẹmu. 13Ẹ̀ dákẹ́, gbogbo ẹran-ara níwájú Olúwa: nítorí a jí i láti ibùgbé mímọ́ rẹ̀ wá.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.