Sekariah 2:4
Zechariah 2:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó si wí fún un pé, “Sáré, sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin yìí wí pé, ‘A ó gbé inú Jerusalẹmu bi ìlú ti kò ní odi, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn àti ohun ọ̀sìn inú rẹ̀.
Zechariah 2:4 in English
Zechariah 2:4 · Berean Standard Bible
and said to him, “Run and tell that young man: ‘Jerusalem will be a city without walls because of the multitude of men and livestock within it.
Context
2Mo sí wí pé, “Níbo ni ìwọ ń lọ?”
O sí wí fún mí pé, “Láti wọn Jerusalẹmu, láti rí iye ìbú rẹ̀, àti iye gígùn rẹ̀.” 3Sì kíyèsi i, angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, angẹli mìíràn si jáde lọ pàdé rẹ̀. 4Ó si wí fún un pé, “Sáré, sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin yìí wí pé, ‘A ó gbé inú Jerusalẹmu bi ìlú ti kò ní odi, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn àti ohun ọ̀sìn inú rẹ̀. 5Olúwa wí pé: Èmi ó sì jẹ́ odi iná fún un yíká, èmi ó sì jẹ́ ògo láàrín rẹ̀.’ 6“Wá! Wá! Sá kúrò ni ilẹ̀ àríwá,” ni Olúwa wí, “nítorí pé bí afẹ́fẹ́ mẹ́rin ọ̀run ni mo tú yín káàkiri,” ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.