Sekariah 2:3
Zechariah 2:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sì kíyèsi i, angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, angẹli mìíràn si jáde lọ pàdé rẹ̀.
Zechariah 2:3 in English
Zechariah 2:3 · Berean Standard Bible
Then the angel who was speaking with me went out, and another angel came out to meet him
Context
1Mó si tún gbé ojú mi, sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ọkùnrin kan ti o mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ rẹ̀. 2Mo sí wí pé, “Níbo ni ìwọ ń lọ?”
O sí wí fún mí pé, “Láti wọn Jerusalẹmu, láti rí iye ìbú rẹ̀, àti iye gígùn rẹ̀.” 3Sì kíyèsi i, angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, angẹli mìíràn si jáde lọ pàdé rẹ̀. 4Ó si wí fún un pé, “Sáré, sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin yìí wí pé, ‘A ó gbé inú Jerusalẹmu bi ìlú ti kò ní odi, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn àti ohun ọ̀sìn inú rẹ̀. 5Olúwa wí pé: Èmi ó sì jẹ́ odi iná fún un yíká, èmi ó sì jẹ́ ògo láàrín rẹ̀.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.