Sekariah 14:20
Zechariah 14:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ náà ni “mímọ́ sí Olúwa” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ.
Zechariah 14:20 in English
Zechariah 14:20 · Berean Standard Bible
On that day, HOLY TO THE LORD * will be inscribed on the bells of the horses, and the cooking pots in the house of the LORD will be like the sprinkling bowls before the altar.
Context
18Bí ìdílé Ejibiti kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò; ààrùn náà yóò wà, tí Olúwa yóò fi kọlù àwọn kèfèrí tí kò gòkè wá láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà. 19Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Ejibiti, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́. 20Ní ọjọ́ náà ni “mímọ́ sí Olúwa” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ. 21Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jerusalẹmu àti ni Juda yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rú ẹbọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kenaani kò ní sí mọ́ ni ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.