Sekariah 12:11
Zechariah 12:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńlá ńlá yóò wà ni Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hadadi Rimoni ni àfonífojì Megido.
Zechariah 12:11 in English
Zechariah 12:11 · Berean Standard Bible
On that day the wailing in Jerusalem will be as great as the wailing of Hadad-rimmon in the plain of Megiddo.
Context
9Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jerusalẹmu.” 10“Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dafidi àti sórí Jerusalẹmu, wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń ṣọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀. 11Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńlá ńlá yóò wà ni Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hadadi Rimoni ni àfonífojì Megido. 12Ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀, ìdílé, kọ̀ọ̀kan fun ara rẹ, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dafidi lọ́tọ̀; àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Natani lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ́. 13Ìdílé Lefi lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Ṣimei lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.