Native Bible

Zechariah 11:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé Olúwa.

Zechariah 11:13 in English

Zechariah 11:13 · Berean Standard Bible

And the LORD said to me, “Throw it to the potter”—this magnificent price at which they valued me. So I took the thirty pieces of silver and threw them to the potter in the house of the LORD.

Context

11Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran náà tí ó dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ Olúwa ni. 12Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi. 13Olúwa sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé Olúwa. 14Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrín Juda àti láàrín Israẹli. 15Olúwa sì wí fún mi pé, “Tún mú ohun èlò aṣiwèrè olùṣọ́-àgùntàn kan sọ́dọ̀ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.