Sekariah 11:12
Zechariah 11:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi.
Zechariah 11:12 in English
Zechariah 11:12 · Berean Standard Bible
Then I told them, “If it seems right to you, give me my wages; but if not, keep them.” So they weighed out my wages, thirty pieces of silver.
Context
10Mo sì mu ọ̀pá mi, ti a ń pè ní Oore-ọ̀fẹ́, mo ṣẹ́ si méjì, ki èmi bá lè da májẹ̀mú mi tí mo tí bá gbogbo àwọn ènìyàn náà dá. 11Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran náà tí ó dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ Olúwa ni. 12Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi. 13Olúwa sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé Olúwa. 14Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrín Juda àti láàrín Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.