Orin Solomoni 7:4
Song of Songs 7:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin. Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu. Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni tí ó kọ ojú sí Damasku.
Song of Songs 7:4 in English
Song of Songs 7:4 · Berean Standard Bible
Your neck is like a tower made of ivory; your eyes are like the pools of Heshbon by the gate of Bath-rabbim; your nose is like the tower of Lebanon, facing toward Damascus.
Context
2Ìdodo rẹ rí bí àwo
tí kì í ṣe aláìní ọtí,
ìbàdí rẹ bí òkìtì alikama
tí a fi lílì yíká. 3Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjì
tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín. 4Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin.
Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni
ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu.
Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni
tí ó kọ ojú sí Damasku. 5Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká,
bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká
a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn. 6Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó
báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.