Orin Solomoni 4:2
Song of Songs 4:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀; olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́; kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró.
Song of Songs 4:2 in English
Song of Songs 4:2 · Berean Standard Bible
Your teeth are like a flock of newly shorn sheep coming up from the washing; each has its twin, and not one of them is lost.
Context
1Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi!
Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà!
Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ
irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́.
Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi. 2Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò
tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀;
olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́;
kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró. 3Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó;
ẹnu rẹ̀ dùn.
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate
lábẹ́ ìbòjú rẹ. 4Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi,
tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra;
lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún (1,000) àpáta kọ́,
gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.