Native Bible

Ruth 4:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ayé ìgbàanì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàṣípàrọ̀ ohun ìní fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnìkejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á. Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Israẹli fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀.

Ruth 4:7 in English

Ruth 4:7 · Berean Standard Bible

Now in former times in Israel, concerning the redemption or exchange of property, to make any matter legally binding a man would remove his sandal and give it to the other party, and this was a confirmation in Israel.

Context

5Nígbà náà ni Boasi sọ wí pé, “Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Naomi àti lọ́wọ́ Rutu ará Moabu, ìwọ gbọdọ̀ fẹ́ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀.” 6Nígbà náà ni ọkùnrin náà dáhùn sí èyí pé, “Nípa ti èyí, èmi kò le è rà á padà, nítorí pé, ọmọ rẹ̀, ọkùnrin yóò wá jẹ́ ajogún àwọn ohun ìní mi pẹ̀lú. Rà á fún ara rẹ, èmi kò le ṣe é.” 7Ní ayé ìgbàanì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàṣípàrọ̀ ohun ìní fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnìkejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á. Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Israẹli fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀. 8Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún Boasi wí pé, “Ìwọ rà á fúnra rẹ̀,” ó yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀. 9Nígbà náà ni Boasi wí fún àwọn àgbàgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, “Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimeleki àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì: Maloni àti Kilioni lọ́wọ́ Naomi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.