Rutu 3:16
Ruth 3:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Rutu dé ilé Naomi ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, “Báwo ni ó ti rí ọmọbìnrin mi?” Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún un fún ìyá ọkọ rẹ̀.
Ruth 3:16 in English
Ruth 3:16 · Berean Standard Bible
When Ruth returned to her mother-in-law, Naomi asked her, “How did it go, my daughter?” Then Ruth told her all that Boaz had done for her.
Context
14Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n ó dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí ẹnìkínní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀. Boasi sì sọ fún un wí pé, “Má ṣe jẹ́ kí ó di mí mọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀ ìpakà.” 15Ó sì tún wí fún un pé, “Mú aṣọ ìborùn rẹ tí o dà bora, kí o tẹ̀ ẹ sílẹ̀.” Rutu sì ṣe bẹ́ẹ̀, Boasi sì wọn òsùwọ̀n ọkà barle mẹ́fà sí i, ó sì gbé e rù ú. Nígbà náà ni ó padà sí ìlú. 16Nígbà tí Rutu dé ilé Naomi ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, “Báwo ni ó ti rí ọmọbìnrin mi?”
Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún un fún ìyá ọkọ rẹ̀. 17Ó fi kún un wí pé, “Ó sọ fún mi wí pé, ‘Má ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ ní ọwọ́ òfo, nítorí náà, ó fún mi ní ìwọ̀n ọkà barle mẹ́fà.’ ” 18Naomi sì wí fún un pé, “Dúró, ọmọbìnrin mi títí tí ìwọ yóò fi mọ bí ohun gbogbo yóò ti rí, nítorí pé ọkùnrin náà kò ní sinmi títí tí ọ̀rọ̀ náà yóò fi yanjú lónìí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.