Rutu 3:12
Ruth 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítòótọ́ ni mo wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó súnmọ́ ọ ju ti tèmi lọ.
Ruth 3:12 in English
Ruth 3:12 · Berean Standard Bible
Yes, it is true that I am a kinsman-redeemer, but there is a redeemer nearer than I.*
Context
10Boasi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fihàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà. 11Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù. Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́n ní obìnrin oníwà rere. 12Nítòótọ́ ni mo wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó súnmọ́ ọ ju ti tèmi lọ. 13Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí Olúwa ti ń bẹ láààyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.” 14Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n ó dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí ẹnìkínní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀. Boasi sì sọ fún un wí pé, “Má ṣe jẹ́ kí ó di mí mọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀ ìpakà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.