Rutu 2:9
Ruth 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkígbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.”
Ruth 2:9 in English
Ruth 2:9 · Berean Standard Bible
Let your eyes be on the field they are harvesting, and follow along after these girls. Indeed, I have ordered the young men not to touch you. And when you are thirsty, go and drink from the jars the young men have filled.”
Context
7Ó sọ wí pé, ‘Kí ń jọ̀wọ́ jẹ́ kí òun máa ṣá ọkà lẹ́yìn àwọn olùkórè.’ Ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ kárakára láti òwúrọ̀ títí di ìsinsin yìí nínú oko àyàfi ìgbà tí ó lọ láti sinmi fún ìgbà díẹ̀ lábẹ́ ibojì.” 8Nígbà náà ni Boasi sọ fún Rutu pé, “Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣá ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi. Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi. 9Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkígbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.” 10Rutu wólẹ̀, ó sì wí fún Boasi pé, “Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsi mi, èmi àjèjì àti àlejò?” 11Boasi sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàrín àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.