Native Bible

Ruth 2:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Boasi sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàrín àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí.

Ruth 2:11 in English

Ruth 2:11 · Berean Standard Bible

Boaz replied, “I have been made fully aware of all you have done for your mother-in-law since the death of your husband, how you left your father and mother and the land of your birth, and how you came to a people you did not know before.

Context

9Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkígbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.” 10Rutu wólẹ̀, ó sì wí fún Boasi pé, “Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsi mi, èmi àjèjì àti àlejò?” 11Boasi sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàrín àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí. 12Kí Olúwa kí ó san ẹ̀san ohun tí ìwọ ṣe fún ọ. Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò.” 13Rutu sì fèsì wí pé, “Kí èmi kí ó máa rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ rẹ síwájú sí i olúwa mi. Ìwọ ti tù mí nínú nípa sísọ ọ̀rọ̀ rere sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tó ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.