Native Bible

Ruth 1:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Maloni àti Kilioni náà sì kú, Naomi sì wà láìsí ọkọ tàbí ọmọ kankan fún un mọ́.

Ruth 1:5 in English

Ruth 1:5 · Berean Standard Bible

both Mahlon and Chilion also died, and Naomi was left without her two sons and without her husband.

Context

3Ní àsìkò tí wọ́n ń gbé ibẹ̀, Elimeleki, ọkọ Naomi kú, ó sì ku òun pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì. 4Wọ́n sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ará Moabu méjì, orúkọ ọ̀kan ń jẹ́ Oripa, èkejì sì ń jẹ́ Rutu. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti gbé níbẹ̀ fún bí ọdún mẹ́wàá, 5Maloni àti Kilioni náà sì kú, Naomi sì wà láìsí ọkọ tàbí ọmọ kankan fún un mọ́. 6Nígbà tí Naomi gbọ́ ní Moabu tí ó wà wí pé Olúwa ti bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò nípa fífún wọn ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ. Ó sì dìde pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì láti padà sí ìlú rẹ̀. 7Òun pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì ni wọ́n jọ fi ibi tí ó ń gbé sílẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn padà sí ilẹ̀ Juda.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.