Native Bible

Romans 7:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa kíkú ohun tó so wá pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í ṣe ní ìlànà àtijọ́ tí ìwé òfin gùnlé.

Romans 7:6 in English

Romans 7:6 · Berean Standard Bible

But now, having died to what bound us, we have been released from the law, so that we serve in the new way of the Spirit, and not in the old way of the written code.

Context

4Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kristi, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run. 5Nítorí ìgbà tí a wa nípa ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nípa ti òfin, ma ń ṣiṣẹ́ nínú wa, tí a sì ń so èso tí ó yẹ fún ikú. 6Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa kíkú ohun tó so wá pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í ṣe ní ìlànà àtijọ́ tí ìwé òfin gùnlé. 7Ǹjẹ́ àwa o ha ti wí, nígbà náà? Òfin ha ń ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n èmi kì bá tí mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, bí kò ṣe nípa òfin. Èmi kì bá tí mọ ojúkòkòrò, bí kò ṣe bí òfin ti wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.” 8Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ sì ti ipa òfin rí ààyè ṣiṣẹ́ onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú mi. Nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ikú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.