Romu 7:5
Romans 7:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ìgbà tí a wa nípa ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nípa ti òfin, ma ń ṣiṣẹ́ nínú wa, tí a sì ń so èso tí ó yẹ fún ikú.
Romans 7:5 in English
Romans 7:5 · Berean Standard Bible
For when we lived according to the flesh, the sinful passions aroused by the law were at work in our bodies, bearing fruit for death.
Context
3Nígbà náà, bí ó bá fẹ́ ọkùnrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láààyè, panṣágà ní a ó pè é. Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin náà, kí yóò sì jẹ́ panṣágà bí ó bá ní ọkọ mìíràn. 4Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kristi, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run. 5Nítorí ìgbà tí a wa nípa ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nípa ti òfin, ma ń ṣiṣẹ́ nínú wa, tí a sì ń so èso tí ó yẹ fún ikú. 6Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa kíkú ohun tó so wá pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í ṣe ní ìlànà àtijọ́ tí ìwé òfin gùnlé. 7Ǹjẹ́ àwa o ha ti wí, nígbà náà? Òfin ha ń ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n èmi kì bá tí mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, bí kò ṣe nípa òfin. Èmi kì bá tí mọ ojúkòkòrò, bí kò ṣe bí òfin ti wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.