Native Bible

Romans 4:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “A kà á sí òdodo fún un,” ni a kọ kì í ṣe nítorí tirẹ̀ nìkan.

Romans 4:23 in English

Romans 4:23 · Berean Standard Bible

Now the words “it was credited to him” were written not only for Abraham,

Context

21pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀. 22Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un. 23Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “A kà á sí òdodo fún un,” ni a kọ kì í ṣe nítorí tirẹ̀ nìkan. 24Ṣùgbọ́n nítorí tiwa pẹ̀lú. A ó sì kà á sí fún wa, bí àwa bá gba ẹni tí ó gbé Jesu Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú gbọ́. 25Ẹni tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde nítorí ìdáláre wa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.