Native Bible

Romans 16:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi Tertiu tí ń kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa.

Romans 16:22 in English

Romans 16:22 · Berean Standard Bible

I, Tertius, who wrote down this letter, greet you in the Lord.

Context

20Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Satani mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín. 21Timotiu alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lukiu, àti Jasoni, àti Sosipateru, àwọn ìbátan mi, kí yín. 22Èmi Tertiu tí ń kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa. 23Gaiusi, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó ṣe náà fi ìkíni ránṣẹ́. Erastu, ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ìṣúra ìlú, àti arákùnrin wa Kuartu fi ìkíni wọn ránṣẹ́.* 25Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.