Romu 14:16
Romans 14:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sọ̀rọ̀ ohun tí ẹ mọ̀ sí rere ní búburú.
Romans 14:16 in English
Romans 14:16 · Berean Standard Bible
Do not allow what you consider good, then, to be spoken of as evil.
Context
14Mo mọ̀ dájú gbangba bí ẹni tí ó wà nínú Jesu Olúwa pé, kò sí ohun tó ṣe àìmọ́ fún ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ka ohunkóhun sí àìmọ́, òun ni ó ṣe àìmọ́ fún. 15Bí inú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí oúnjẹ rẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́. Má ṣe fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kristi kú fún di ẹni ègbé. 16Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sọ̀rọ̀ ohun tí ẹ mọ̀ sí rere ní búburú. 17Nítorí ìjọba ọ̀run kì í ṣe jíjẹ àti mímu, bí kò ṣe nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Ẹ̀mí Mímọ́, 18nítorí ẹni tí ó bá sin Kristi nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.